Adẹ̀yìnmú Ẹgbẹ́ Agbábáọ̀lù Algeria, Bedrane Kòní Leè kópa Nínú Ìdíje Ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ikọ̀ Super Eagles.
Adeyinmu ẹgbẹ́ agbábáọ̀lù Algeria, Abdelkader Bedrane kòní leè kópa ninu Idije
Ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ̀rẹ́ pẹ̀lú ikọ̀ tí Super Eagles orílè-èdè Nàìjíríà.
Bí ìròyìn se ròó lórí wẹ́búsáìtì ti Algeria Football Federation, ọmọ ọgbọ̀n ọdún náà fi
orókún ṣèse nígbàtí ó ń gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú ikọ̀ Desert Foxes ti Algeria tí wọ́n
ṣì borí pẹ̀lú ayòkan sódo ní ọjó ẹ̀tí ní Pápá ìseré Miloud Hadefi ní ìlú Oran.
Ó ti padà lọ sí Saudi Arabia Professional Football League outfit, Damac rẹ̀
nítorí Ìfarapa náà. O sì ti gbá bọ́ọ̀lù lẹ́ẹ̀mẹ́wàá fún orílẹ̀-èdè rẹ̀ tó tí gba ife
ẹ̀yẹ ti adúláwọ̀ náà ni ìgbà méjì.
Bedrane pẹ̀lú àwọn tó borí ní FIFA Arab Cup ni ọdún 2021.
Ìdíje tèní, ọjọ́ Ìṣẹ́gun yóò wáyé ní aago mẹ́jọ ní Pápá ìseré Miloud Hadefi ní ìlú Oran.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply