Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Nàìjíríà Sanwó Ìtanràn Fún Àwọn ènìyàn Mẹ́rìnléláàdọ́rin Tí Àwọn Ọlọ́pàá Fí Ìyà Àìtọ́ Jẹ́

0 351

Ìjọba Nàìjíríà tí sàn owo tó jù igba o le mejidinlọgọrin miliọnu naira (289m) fun àwọn mẹrinlelaadọrin (74) lórí bí wọn se tẹ ẹtọ  ọmọniyan  loju mọlẹ ati ẹsun iwa ọdaju tí  awọn ọlọ́pàá kàn hu si wọn .

Ìgbìmọ̀ Ìwádìí olómìnira lórí àwọn ẹsùn ẹtọ ọmọnìyàn se iwadi bi awọn ikọ̀ àwọn ọlọ́pàá kàn [Squad Special Anti-Robbery Squad (SARS)] tí wọ́n sí fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣé baṣu baṣu náà ní ìwé sọwedowo ní Abùjá, Olú-ìlú orílẹ-èdè náà.

Èyí tẹle Ìwọ́de tí wọ́n ṣe jakejado orílẹ-èdè yíì ní ọdún 2020 láti fi òpin sí ikọ̀ àwọn ọlọ́pàá wọn yìí, ti wọ́n fi ìṣòro rẹ sọ #EndSARS

Ọkàn nínú àwọn ìbéèrè wọ́n ní idasilẹ ìgbìmọ̀ ti yóò ṣé ìwádìí àti ìdájọ bí àwọn ọlọ́pàá náà tí ṣé lo agbára tí a gbé lé wọn lọwọ lọnà tí kò bá òfin mu.


Salamatu Suleiman, Alága Ìgbìmọ̀ àti Alàkóso tí ẹtọ ọmọnìyàn ni orílẹ-èdè Nàìjíríà, níbí isànwò Ẹlẹẹkeji irú rẹ̀, gboriyin fún ìgbìmọ̀ náà lábẹ́ Adájọ Suleiman Galadima, fún ìgbìyànjú wọn láti ọdún méjì sẹyìn.

O tẹ síwájú nínú ọrọ rẹ pé, ìgbìmọ̀ náà ni ànfàní láti gbọ́ àwọn ẹjọ́ igba o le mẹrinlelaadọrun (294) ti wọ́n sì tí ṣé ìdájọ lórí ìgbà o le méjìlelaadọrun (292) Ìgbìmọ̀ náà ti sàn owo tó le ní irinwo mílíọ̀nù náírà (431m) fún àwọn merinlelaadọrun (94) lábẹ́ ìgbìmọ̀ náà.
O sí ṣe ìlérí pé, ìgbìmọ̀ náà yóò tẹ̀síwájú níbí idaabobo àwọn àrà ìlú lórí ẹtọ ọmọnìyàn.


Adájọ Galadima tún rọ àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ láti yà owo sọtọ fún ìgbìmọ̀ náà láti ṣé iṣẹ́ wọn bí iṣẹ ni gbogbo ipinlẹ lórílẹ̀ èdè yìí.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button