Take a fresh look at your lifestyle.

Ìbúra Fún Ààrẹ Angola Fún Ìgbà Kejì Lórí Ààlèfà

0 280

 

Ààrẹ Angola João Lourenço ni wọ́n yóò máa ṣe Ìbúra fún gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ fún ìgbà kejì lórí Ààlèfà, bí ó ti lẹ́ jẹ pe kinkinni l’ori fi kò yọ nínú èéto ìdìbò Ẹlẹ́kejìí tí ìfigà gbà ga láàrin àwọn Olùdíje lé kenka.

Ẹgbẹ Òṣèlú rẹ MPLA ni wọn ti ń jẹ Ààrẹ láti ìgbà tí Orílẹ-èdè wọ́n ti gbá Òmìnira lọwọ Portugal ní 1975.

Ọgbẹ́ní Lourenço ṣé àpèjúwe esi ìbò náà “bíi ìbò afọ́kàn tán.” Nítorí ìdí èyí, ó ní ó pọn dándán fún ohùn láti ṣètò tí ó Kẹ̀sẹ́járí fún ọjọ iwájú àwọn Ọdọ Orílẹ-èdè náà tí wọn ń póngbẹ fún iyìpadà to yànrántí àti ìgbésí ayé tí ó ní ìtùnmọ.

Ìròyìn fi tó wà létí wí pé Ààrẹ pòlóngò gidi gidi gan-an fún ìjọba tí kò ní gbà jẹ gùdù jẹrà láàyè.

 

Olubunmi Adeyẹmọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button