Ẹka ìpínlẹ̀ Nassarawa ti ẹgbẹ́ òsèlú APC ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí alága àgbà ẹgbẹ́ náà, Asòfin Abdullahi Adamu láti parí aáwọ̀ nípa pípáàrọ̀ olùdíje lọ́nà t́i kò bá òfin mu, lẹ́yìn ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ náà tí ó kojá.
Ọ̀gbẹ́ni Àlíyù Béllò tí ó jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ náà ni ó pe ìpè náà nígbà tí ó kọ̀wọ́ rìn pẹ̀lú igbákejì alága ti ààrin gbìngbìn àréwá, láti se ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn abẹnu gan-an ẹgbẹ́ náà.
Béllò pa àrọwà sí àwọn tí ó fìdí rẹmi nínú ìbò abẹ́lé náà, àti pé wọ́n ní láti fọwọ́ sowọ́pọ̀ fún ìjáwé olúborí ẹgbẹ́ náà níbi ìbò àpapọ̀ ọdún 2023.
Bawa- Rijau, ní ìdáhùn sí ọ̀rọ̀ náà fi dá wọn lójú pé, àtúnse yóò wáyé, ó sì fi dáwọn lójú pé ẹgbẹ́ náà yó̀o jáwé olúborí ní ìpínlẹ̀ Nassarawa àti ìbò àpapọ̀ ọdún 2023.
Leave a Reply