Take a fresh look at your lifestyle.

Gbajúgbajà òṣèré Ada Ameh di olóògbé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 296

Gbajúgbajà òṣèré tí gbogbo ènìyàn mọ̀ nípasẹ̀ eré ẹbí  olókìkí ‘The Johnsons’ ti di olóògbé ní ọjọ́ Àìkú,ọjọ́ kẹtàdín-lógún, Oṣù Keje, ọdún 2022 ní ilé-ìwòsàn kan ní ìpínlẹ̀ Delta.

Ada Ameh, ẹni ọdun mejidin-laadọta, jẹ oṣere Naijiria ti o ti lo ju ogun ọdun lọ ni ile-iṣẹ fiimu Naijiria ati pe ti a mọ pupọ julọ fun ipa to ko bi Anita ninu fiimu ọdun1996 ti akole rẹ jẹ “Domitilla” ati bi Emu Johnson ninu ere ori tẹlifisiọnu ti o gba ami-eye ni Naijiria ti akole rẹ n jẹ ‘The Johnsons’.

Agba oṣere Nollywood naa ni ọmọbinrin kan ti o ku ni Oṣu Kẹwa, ọdun 2020.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button