Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Bùhárí kí Òṣèré Nollywood Olú Jacobs,kú ayẹyẹ ọgọ́rin ọdún

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 396

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárì ti dara pọ̀ mọ́ mílíọ́nù ènìyàn,Nollywood àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n òṣèré,nilé àti lókè òkun, láti kí òṣèré orí ìtàgé  àti amóhùnmáwòrán, Olú Jacobs, fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọrin ọdún rẹ̀ tí yóò wáyé ní ọjọ́ kọkànlá oṣù keje.

Eyi di mimo ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ rẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adesina,  fi sita lọjọ Aiku,o ṣajọyọ fun idile Jacobs, pẹlu iyawo rẹ, to tun jẹ gbajugbaja oṣere, Joke Silva, ati awọn ọrẹ wọn lasiko ayẹyẹ naa, eyi ti o to ki wọn dupẹ lọwọ Ọlọrun fun itoju, itọsọna ati aabo.

 

Bi oṣere naa ṣe pe ọgọrin ọdun,Aarẹ sọ pe o maa n lo ọgbọn lati se awọn ipa rẹ,sọ awọn nkan ti ole di irọrun ti o si n fun ọdọ ati agba loye,ti kii ya aṣa, ẹya ati ẹsin kankan sọtọ,ti o si di ilu mọọka ni gbogbo orilẹ-ede ati ikọja.

Aarẹ gbadura pe ki ọlọrun Eledumare fun oun ni ilera to peye, emi gigun ati iduroṣinṣin ninu isin Olorun, ọgbọn ori, ati ifẹ eda eniyan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button