Take a fresh look at your lifestyle.

AfDB yóò ran Áfíríkà lọ́wọ́ Láti Dènà ìyàn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 1,980

Ìgbìmọ̀ Alákòóso Ilé-ìfowópamọ́ Ìdàgbàsókè Áfíríkà (AfDB), ti fọwọ́sí ohun èlò bílíọ́nù kan àti ààbọ̀ dọ́là láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà láti dènà ìdààmú oúnjẹ tí ó ń bọ̀.

Gẹgẹ bi idaduro ipese ounjẹ ti o waye latari ogun to ṣẹlẹ laarin Rọsia ati Ukireeni, Afirika ko ni anfaani si awọn ounjẹ to to ọgbọn miliọnu tọọnu mẹtiriki, paapaa alikama, agbado, ati awọn ẹwa soya ti wọn n ko wọle lati awọn orilẹ-ede mejeeji.

Biliọnu kan ati aabọ Ile-iṣẹ iṣelọpọ Ounjẹ pajawiri ti AfDB yoo pese ogun miliọnu agbẹ alabọọde ilẹ Afirika pẹlu awọn irugbin pẹlu ifọwọsi AFDB,ti  ajilẹ yoo si wa larọwọto  ati lati pese miliọnu mẹjidin-logoji tọọnu  ounjẹ.

Nigba to n sọrọ lori idagbasoke naa, Aarẹ AfDB, Dokita Akinwumi Adesina, sọ pe banki naa yoo pese biliọnu kan ati ida meta dọla ti  yoo si gba igba miliọnulati ọdọ awọn oluranlọwọ ẹgbẹ meji.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button