Ọ̀gá àgbà fún àwọn Òṣìṣẹ́ Ilé-ogun (COAS),ajagun Faruk Yahaya ti rọ àwọn ọmọ-ogun Nàìjíríà láti dúró ṣinṣin lórí ìpinnu wọn àti dídojúkọ àṣẹ òfin iṣẹ́ tí wọ́n gbà èyí tí ó jẹ́ ìdáábòbò ẹ̀tọ́ agbègbè orílẹ̀-èdè àti ìdáábòbò ará ìlú nípa pípèsè ààbò tópéye jákèjádò orílẹ̀-èdè.
COAS ṣalaye yi ni Uyo, lakoko ti o n ba awọn ọmọ ogun sọrọ lakoko irin-ajo iṣẹ rẹ ti 2 Brigade Area of Responsibility (AOR) ni ọjọ kẹjọ,ọjọ iṣegun, Oṣu Kẹta, ọdun 2022.
Ajagun Mohammed Inuwa ṣalaye ipo aabo ni agbegbe gbogbogbo fun ọga agba fun awọn ajagun ni kete ti o gbalajo rẹ.
Gege bi alaye ti Oludari Ibaṣepọ Gbogbogbo awọn ọmọ ogun,ajagun Onyema Nwachukwu ṣe, COAS sọ pe eto idibo yoo bẹrẹ laipe ni ayika orilẹ-ede o kilọ pe awọn ọmọ-ogun gbọdọ yago fun didasi ọrọ oṣelu kankan.
Olori ile-ogun naa tẹnumọ ipa ti awọn ọmọ-ogun lakoko idibo, gẹgẹbi ti atilẹyin fun ọlọpa Naijiria, eyiti o jẹ aṣoju asiwaju ninu eto aabo idibo.
Leave a Reply