Ẹgbẹ to n risi Ilọsiwaju Eto ifetosomo bibi ni orile -ede Naijiria ti sọ pe eto naa yoo din iku abiyamo ku ni ida ogbon.
Alaga Igbimọ Isakoso Imọ-ẹrọ ẹgbẹ ohun, Dokita Ejike Oji,so eleyi di mimo lakoko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn oniroyin ni ilu Abuja ni ọjọ isegun.
Alaga naa ṣalaye pe,ifetosomo bibi se Pataki pupo fun awọn iya ati awọn ọmọde. Oji ti o tun salaye pataki ifetosomo bibi fun awọn ebi, sọ pe o wa ni gbogbo awọn ile-iṣẹ ilera alakọbẹrẹ.
Gege bi o ti sọ,ifetosomo bibi jẹ ọfẹ ti o si wa kaakiri arowoto.
Leave a Reply