Take a fresh look at your lifestyle.

Ààre Bùhárí yóò ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọjọ́bọ̀

Fauziat Eyitayọ Oyetunji

0 302

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Mùhámmádù Bùhárí yóò ṣàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Ògùn, gúúsù ìwọ oòrùn ní ọjọ́bọ̀ ,ọjọ́ kẹtàlá,ọṣù kínní,ọdún 2022.

Lakoko abẹwo naa, Aarẹ Buhari yoo ṣe ifilọlẹ awọn iṣẹ akanṣe kan ti Gomina Dapọ Abiọdun ṣe.

Wọn yoo gbalejo aarẹ Buhari ni Ọgba Gateway City Gate Monument Park, Sagamu Interchange, ni aago mẹwa aarọ nibi ti ise akanse akọkọ yoo ti bẹrẹ.

Akọwe agba fun gomina,Kunle Sọmọrin sọ pe awọn alejo yoo ti joko ni agogo mẹsan abọ owurọ  ni Ẹnubode Ilu loju opopona,ti gbogbo akiyesi awọn ilana aabo aarun corona yoo si jẹ imuṣẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button