Take a fresh look at your lifestyle.

ètò ìdìbò 2023:N kò ní àyànfẹ́ kankan tí yóò gba ipò mi-Ààrẹ Buhari

0 352

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà , Muhammadu Buhari  ti ní òun kò ní  ẹnìkankan lọ́kàn  tí yóò gba ipò rẹ̀ nínú ètò ìdìbò tí yóò wáyé  lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fi àlèéfà sílẹ̀ lọ́dún 2023.

Aarẹ Buhari sọrọ yii lasiko ifọrọwanilẹnuwo to waye ni ile -isẹ mohun-maworan ti Channels lasalẹ ỌjọRu.

Aarẹ Buhari tun sọ pe  ; ”Ko si ohun to kan mi nipa ẹni ti ẹgbẹ́ oselu All Progressive Congress (APC)ba yan gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ wọn, nitori ẹni ti ẹgbẹ APC ba yan ni maa faramọ́.“.

“Bakan naa, ki ẹnikankan , maa waa ba mi pe ki n wa jẹ́ ẹlẹ́rìí oun ni ile-ẹjọ, nitori pe, onitọhun yoo kan àbùkù ni.Nitori pe, gbogbo ohun to se pataki lo ti wa ni ninu iwe.”

NIPA ORILẸ EDE NAIJIRIA
Aarẹ Buhari, ni ohun ko ni da si ẹjọ́  adari ẹgbẹ, Indigenous People of Biafra (IPOB), Nnamdi Kanu,  to wa nile ẹjọ́.Nitori naa, anfaani wa fun Kanu lati gbeja ara rẹ nile -ẹjọ́.

Aarẹ Buhari wa fi aidunnu rẹ han bi  Kanu ati ikọ IPOB se n ba orukọ orilẹ ede Naijria jẹ́ nilẹ okeere.

“ Bi Kanu se n bu ẹnu atẹ lu ijọba wa lati ilẹ okeere ko dara to, o yẹ ki kanu wa si orilẹ ede Naijria, ki o maa tako ijọba wa, yoo ni anfaani lati jẹ ki a fi eti si ohun ti o n sọ.

“ Sugbọn awọn eniyan n pariwo pe, ki a fi i silẹ  sugbọn a o ni fi silẹ.”

Atuns enipa eto idibo

Aarẹ Buhari ni , oun ko fọwọsi atunse lori eto idibo ti ile igbimọ asoju-sofin gbe wa siwaju rẹ nitori pe, ko fun gbogbo awọn ẹgbẹ oselu ni anfaani lati lee yan awọn oludije ti wọn nifẹẹ si, ti yoo maa soju wọn.

OLỌPAA IPINLẸ

Aarẹ ni sisé idasilẹ ọlọpaa ibilẹ ko lee yanju isoro to n dojukọ eto aabo lorilẹ ede Naijria.

o ni awọn gomina lee maa lo wọn lati maa fi dun ìkookò mọ awọn to n tako wọn.

”Sise idasilẹ awọn ọlọpaa ibilẹ ki i se ọna ti a le lo lati fi yanju isoro to n dojukọ eto aabo lorilẹ ede Naijria.Iọ wadii nipa ibasepọ to wa laarin ijọba ibilẹ ati  ipinlẹ .Njẹ awọn gomina n jẹ ki awọn ijọba ibilẹ se ojuse wọn , bo se wa labẹ ofin bi?

”Jẹ ki awọn eniyan to wa ni ijọba ibilẹ sọ nipa ija to  maa n waye laarin wọn ati ijọba ipinlẹ ”

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button