Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ọlọ́pàá Kẹnya Mú àwọn tí wọ́n furasí mẹ́jọ kan lórí ìkọlù Lámù

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 320

Àwọn ọlọ́pàá Kẹnya ti mú ènìyàn mẹ́jọ tí ó níṣe pẹ̀lú ìkọlù ọjọ́ ajé ní agbègbè Lámù ní etíkùn Kẹnya, nínú èyítí  ènìyàn mẹ́fà pàdánù ẹ̀mí wọn, tí wọ́n sì jó ilé níná.

Awọn ọlọpa ti mu awọn mẹrin tẹlẹ, wọn si fi atẹjade kan sita ni eyi ti o sọ orukọ eniyan mẹjọ ti wọn mu lori iwadii ipaniyan naa.

Ninu ikọlu naa, to waye laarin  ni alẹ ọjọ Aiku ati owurọ ọjọ aje, wọn ge ọkunrin kan lori.

Wọ́n kó ilé rẹ̀, wọ́n sì yinbọn pa ọkùnrin mìíràn leleyi tí wọ́n rí òkú rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà kan, gẹgẹ bi awọn ọlọpa ṣe sọ.

Lẹyin naa, oku awọn ọkunrin mẹrin miiran ti wọn ti jona, ti wọn di ọwọ wọn, ti wọn  ko si le dawọn mọ mọ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button