Lọ́jọ́ Iṣẹ́gun,ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Ìbàdàn àti àwọn ará ílú péjọ sí Ààfin Pópóyemoja ti Olóògbé Ọba Sálíù Adétúnjí, fún àdúrà ọjọ́ kẹta ọba Olúbàdàn tó wàjà.
Adura naa bẹrẹ ni nnkan bi aago mẹsan owurọ pẹlu isin awọn ọmọ kristiẹni, eleyii ti awọn asaaju lati orisirisi ẹsin pejupesẹ nibẹ, ti Alaga ẹgbẹ ijọ kirisitẹni lapapọ ti ipinlẹ Ọyọ, Apostle Joshua Akinyemiju se adari.
Nibi isin kukuru naa, awọn alufaa rọ awọn ara ilu Ibadan ati ipinlẹ lapapọ lati ṣọkan wọn giri, ki won si maa ranti awọn iwa rere, alaafia, ọgbọn ati idagbasoke to jọba lasiko oloogbe naa.
Leave a Reply