Àjọ NGO Fún Àwon Aláìní,ilé Ìjọsìn àti Àwon Olórí Agbègbè Ní Èbònyì nílé
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àjọ tí kìí ṣe tìjọba, NGO , tí a mọ̀ sí Ebele àti AnyiChucks Foundation ti ṣàfihàn àti ìṣètọrẹ ilé mẹ́tàlé- lógún kan fún Àwọn Aláìní, Àwọn ilé ìjọsìn àti àwọn aṣaájú agbègbè láti pèsè ààbò tó jọjú fún wọn.
Oludasile ajo NGO ọhun, Dokita Ifeanyi Chukwuma Odii lo fi eyi han fawon oniroyin ni Isu ,ni ijoba ibilẹ Onitcha, ni ipinle Ebonyi ni Guusu ila oorun Naijiria lasiko ti won n ṣe afihan awon ile naa.

A o ranti pe Ebele ati AnyiChucks Foundation ti sọ di iṣe rẹ lọdọọdun , lati ṣe iranwọ fun awon ti won ko ni anfaani si itoju ilera ọfẹ fun gbogbo ọmọ Ebonyi ati awon miran, leyin ti o ti fun wọn ni ẹgbẹrun lọna mẹtala (13000) apo irẹsi ati ẹgbẹrun mẹfa igan aṣọ fun awọn ijọba ibilẹ mẹtala ni ipinlẹ naa.
Leave a Reply