Àsàbà yóò ṣagbátẹrù àjọ̀dún eré ìdárayá àpapọ̀ ọdún fún 2022
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè lórí Àwọn eré ìdárayá ti fọwọ́sí Oṣù kọkànlá ọjọ́ kejì sí ìkẹẹ̀dógún, ọdún 2022 ,gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fùn àjọ̀dún àpapọ̀ eré ìdárayá ẹlẹ́ẹ̀kọkànlé-lógún ní Ìpínlẹ̀ Delta ti fi òhùntẹ̀ lu Àsàbà 2022 gẹ́gẹ́ bí Mínisità fún Ìdàgbàsókè Àwọn ọ̀dọ́ àti Àwọn eré ìdárayá.
Sunday Dáre ti ṣe àpèjúwe Ìpínlẹ̀ Delta gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ tí ó ní àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn fún ìdàgbàsókè eré ìdárayá ní orílẹ̀-èdè.

Nigbati o n soro ni Asaba, olu-ilu Delta , nibi ipade igbimọ araọtọ orilẹ-ede fun ere idaraya, Minisita dupe lowo Ipinle naa fun gbigbalejo gbogbo ipade ere idaraya ti o se pataki, o si so wi pe aseyori orile-ede Naijiria ninu ere idaraya ko ni pari laisi iranlowo Ipinle naa, ati ipa pataki awọn elere idaraya rẹ.
Minisita naa gboyìn fun Igbimọ Orilẹ-ede lori Awọn ere idaraya fun ifọkansi ati iduroṣinṣin wọn si idagbasoke ere-idaraya, ati atilẹyin ti oun ati Ile-iṣẹ ti gba ni ọdun meji sẹhin.
Leave a Reply