Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni awọn to pa Sylvester Oromoni, to jẹ ọmọ ile-ẹkọ Dowen to wa ni Lekki ní ipinlẹ Eko kò ní fara ire lọ.
Ọmọ ọdun mejila ọhun, ni a gbọ pe awọn akẹgbẹ seku paa nile ẹkọ to wa , latari bi wọn se se ọmọ ọhun ni ijamba, ni eyi ti o gbẹmi ọmọ naa.
Aarẹ Buhari fi aidunnu rẹ han bi wọn se pa ọmọkunrin ọhun wa nile ẹkọ to wa , wa ni ; “To ba se pe loootọ ni ọmọkunrin naa ku, nipase, bi wọn se fẹ mu wọ inú ẹgbẹ́ okunkun tabi bi wọn se fi ìyà aitọ jẹẹ, iyẹn a gbọdọ wa nnkan se si isẹlẹ buruku ọhun.
“Mo ba awọn ẹbi Oromoni, ijọba ipinlẹ Eko ati orilẹ ede Naijiria kẹdun lori isẹlẹ naa, mo si fi n da wọn loju pe, ao se ikwadii isẹlẹ buruku, ti ao si fi gbogbo awọn to lọwọ ninu isẹlẹ naa jofin. ,”
Aarẹ Buhari wa rọ awọn gbofinro ati ile-isẹ ọlọpaa lati se iwadii finni-finni nipa isẹlẹ ọhun.Ki wọn si fi ọwọ ofin mu gbogbo awọn to lọwọ ninu isẹlẹ naa, laifi da ẹnikankan si.
Leave a Reply