Take a fresh look at your lifestyle.

Àjò ò lè dà bí ilé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 442

Àjọ tó ń rísí ètò   pàjáwìrì ní orílẹ̀-èdè, (NEMA) ní ọjọ́ọ́rú, gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà márùndín-lọ́gọ́rùn ún (95) tí wọ́n ti tàn sí orílẹ̀-èdè Líbíyà, ní pápá ọkọ̀ òfurufú Múrítàlá Muhammed ní ìlú Èkó.

Alhaji Habib Mustapha, Oludari Agba fun NEMA, ti o  ṣoju fun Alakoso ile iṣẹ ti ilu Eko, Ogbeni Ibrahim Farinloye,lo fi idi idagbasoke naa mulẹ ni ilu Eko.

Farinloye sọ pé, àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n gúnlẹ̀ si pápákọ̀ òfuurufú Muritala Muhammed lálẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta, ní nǹkan bí agogo mẹjọ kọja iṣẹju mejidin-logun alẹ́ pẹ̀lú ọkọ̀ òfuurufú Al Buraq pẹlu nọ́ńbà UZ189/16/5A- DMG-MJI AD15:50.

O sọ pe, Ajo Agbaye fun Iṣilọ (IOM)  da wọn  pada wa si orilẹ-ede  nipasẹ eto ipadabọ atinuwa fun awọn  ti o ba bi nnkan yoo ṣe dẹrun funwọn kuro ni orilẹ-ede, ti nnkan o si tun papa rọrun fun wọn, ṣugbọn wọn ko ni anfani lati pada si orile-ede  nigbati irin-ajo wọn ko ri bi wọn ṣe roo.

Farinloye sọ pé, àwọn tí wọ́n padà wá jẹ́ ọgọ́ta, àgbà ọkùnrin, àgbà obìnrin mọkandin-lọgbọn, ọdọkunrin mẹ́ta àti ọ̀dọ́bìnrin kan, pẹ̀lú ọmọ ọwọ́ méjì (ọkùnrin kan àti obìnrin kejì).

O sọ pe laarin awọn ti o pada wa,  awọn ọkunrin meji kan wa ti wọn ni  ipele oriṣiriṣi  ọran ilera.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button