ikọ agbabọọlu orilẹ ede Naijiria, Super Eagles tun ti dẹru ìyà ru akẹgbẹ wọn to wa lati orilẹ ede Cape Verde, iyẹn ikọ agbabọọlu Cape Verde ninu idije ifẹsẹwọnsẹ lati mọ awọn orilẹ ede wo ni yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ bọọlu agbaye ọdún 2021 to n bọ yii.
Papa iṣere Teslim Balogun to wa niluu Eko,ni ikọ Super Eagles ti se bi akọni to lọ soju ogun to bọ, lati yọ ikọ agbabọọlu Cape Verde bii jìga ninu idije to waye ọhun.
Victor Osimhen lo kọkọ gba bọọlu akọkọ ̀sinu àwọ̀n ikọ agbabọọlu Cape Verde , ki a to sẹju pẹrẹ ni Júlio Tavares naa tun daa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju marun un.
Laisi ani ani, orilẹ ede Naijiria ti fakinyọ ninu ipele awọn ti yoo dije ninu eré bọọlu agbaye ti ọdun to n bọ.
Leave a Reply