Wọń ti gba àwọn àguǹbánirọ̀ nímọ̀raǹ láti yàgò fuń àwọn ìriǹ tó lè dá ẹ̀mi wọn légbodò gẹ́gẹ́ bi ìrìn -òde -òru àti ìrìn -àjò láì gba àyè lati ọ̀dọ̀ awọn adarí àjọ naa.
Ninu iroyin kan to jade lati ọdọ adari eto agunbanirọ, ọgagun Shauibu lbrahim; o sọ wi pe ko si ohun to jẹ mọ isinmi ọlọsẹ meji fun awọn agunbanirọ to sẹsẹ wọlé . O se alaye pe ni kete ti gbogbo agunbanirọ ba ti kuro ni ipagọ idanilẹkọọ ni ki wọn farahan nibi ti wọn pin wọn si lati sin orile ede wọn.
Bakan naa, ni oludari ajọ naa, ọgagun Shauibu lbrahim, wa gba awọn agunbanirọ niyanju lati yago fun ìrìn ọ̀gànjọ́ oru. Nitori pe, ẹni ti a ba bí i re, ki rin irin òru ati pe eyi lewu lọpọlọpọ fún wọn.
Tolulope
Leave a Reply