Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbìmọ̀ aṣòfin bẹ̀rẹ̀ àríyànjiyàn ìfọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ Lórí Owó Ìsọdọ̀tun 2022

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 388

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí àwọn ìpilẹ̀ gbogboogbò  Òfin Ìsọdọ̀tun 2022, gẹ́gẹ́ bí apákan  àṣàrò  owó tí ààrẹ Bùhárí gbé  síwájú àpéjọ àpapọ̀ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú  Orílẹ̀ -èdè, ní Ọjọ́bọ̀ ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣagbekalẹ iwe isuna ti o to triliọnu mẹtadin-logun siwaju  Awọn igbimọ  aṣofin, N16,391,023,917,692, ti o si n reti ibuwọlu fun  inawo ọdun  2022.

Diẹ ninu awọn igbimọ aṣofin ti o wa nijoko nibi apejọ ọjọ naa sọsi ọrọ iwe -owo  naa  ti awọn toku gbimọ lati ṣe afikun tiwọn ni Ọjọbọ, ti yoo jẹ ọjọ ikẹhin fun ijiroro naa,  ki owo naa to lọ fun kika ẹlẹẹkeji.

Abẹnugan ile igbimọ aṣofin, Ahmad Lawan rọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ lati ri pe wọn wa nijoko  ni iyẹwu ni ọjọ Ọjọbọ  lati pari ijiroro naa, ki o le tẹsiwaju si ipele ti o tẹle fun asiko  Isuna aabo fun  MDAs.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button