Take a fresh look at your lifestyle.

Eid-Al-Fitr: Ìjọba Naijiria kede Ọjọru 12th,Ọjọbọ 13th fún ìsinmi

Ademọla Adepọju

55

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ti kéde Ọjọ́rú, 12th  àti Ọjọ́bọ̀, 13th fún ìsinmi ọdún Eid-Al-Fitr .

Mínísítà fún ọrọ̀ tó jẹ́ mọ́ abẹ́lé, ọgbẹni Rauf Aregbesola,lo kede rẹ niluu Abuja, lati fi ki awọn musulumi ku ori ire , o wa rọ  gbogbo ọmọ orílẹ ̀ede Naijiria nile ati lẹyin odi lati lo anfaani ayẹyẹ ọdun  Eid-Al-Fitr lati gbadura fun alaafia, isọkan  ati ayidapa lori eto ọrọ aje.

o tun wa rọ gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria lati tẹle ofin , ki wọn si gba ìfẹ́ ,ìfaradà, aanu ati ìpamọ́ra laaye gẹgẹ bi anabi , ojisẹ nla  Mohammed (Ki alaafia Ọlọrun wa pẹlu wa), se paa lásẹ.

O tun wa rọ gbogbo awọn agbofinro ati ajọ eleto aabo lati máa se kaarẹ nipa gbigbogun ti awọn ọlọtẹ ati ọdaran to n da alaafia omi orilẹ ede yii rú.

O tẹsiwaju pe ijọba aarẹ  Muhammadu Buhari ko ni kaarẹ lati ri i pe alaafia pada si orilẹ ede Naijiria, ti eto aabo to mẹhẹ yoo waa di afisẹyin ti eegun n fi asọ.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.