Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko lapa Iwọ-oorun Gusu orilẹ-ede Naijiria, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti rọ awọn olugbe Ipinlẹ Eko ati awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lapapọ lati ni igbagbọ pe ọdun tuntun 2022 yoo jẹ ọdun isọdọtun ati ireti ayọ.
Aṣofin Ọbasa sọrọ iṣiti yii ninu ọrọ ikini rẹ fun ọdun tuntun, nigba ti o n gboriyin fun ẹmi ifarada awọn ọmọ orilẹ-ede yii pẹlu awọn ipenija ti wọn koju ni ọdun 2021, paapaa awọn atunbọtan arun COVID-19, ti gbogbo agbaye naa n koju rẹ bayii.
Oludari Ile Igbimọ Aṣofin naa woye pe ọpọ ileri rere lo wa ninu ọdun tuntun yii, ṣugbon ẹmi iṣọkan wa lo se pataki lati fi gbogun ti awọn ọta ilọsiwaju orilẹ-ede yii. Ati pe ki wọn tẹ siwaju lati maa gbe ogo orilẹ-ede yii ga. O ni:
“Bi mo ṣe n fi asiko yii ki awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ku oriire ọdun tuntun, mo fi n da yin loju pe pẹlu ẹmi iṣọkan wa, a le ni orile-ede rere, gẹgẹ bi nnkan ṣe n dara bayii ni Ipinlẹ Eko, ti i se olu ilu fun ọrọ-aje orilẹ-ede Naijiria. Laisi aniani, ni bayii Ipinlẹ Eko jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ti alaafia n jọba, botilẹ ṣe pe ọpọ eniyan lo n gbe ibẹ, eyi ti o mu u jẹ ilu nla pataki.
Lara awon ohun to ṣokunfa aṣeyori Ipinlẹ Eko ni ọdun 2021 ni ibaṣepọ to fẹsẹ mulẹ to wa laarin awọn ẹka ijọba, ati atilẹyin awọn ara ilu. Ni Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, a n ri daju pe awọn ojuṣe wa, awọn abadofin, awọn aba ati ipinnu wa nii ṣe pẹlu idunnu, aabo ati irọrun awọn ara ilu gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin orilẹ-ede yii.
Laipẹ yii ni a fọwọ si abadofin eto Iṣuna-owo ọdun 2022 ki ijọba le rowo na fun ọdun tuntun, ati abadofin ṣiṣe idasilẹ Fafiti Eto Ẹkọ Ipinlẹ Eko lati le jẹ kori-o-ya fun awọn to ba fe ṣiṣẹ olukọ, ti yoo fi rọrun fun wọn lati fi iwe ẹri wọn tete ri iṣẹ.
Bakan naa la ti fọwọ si ọpọ abadofin miiran ti o ti ṣe Ipinlẹ Eko lanfani, ti o fi wa ni ipo ti ọpọ fi n ṣawo kọṣe. Ile Igbimo Asofin Ipinlẹ Eko pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn tẹwon, ti wọn dantọ, yoo tẹ siwaju lati fakọyọ ninu ọdun 2022 yii”
Aṣofin Ọbasa fi eyi ki awọn olugbe ipinlẹ yii ati ọmọ orilẹ-ede Naijiria ku oriire ọdun tuntun.
Leave a Reply