Ni ibi ayẹyẹ fifi àmì ẹyẹ ìdánilọ́lá ọdún 2024 Music Of Black Origin (MOBO) ti wọn se ni Utilita Arena Sheffield, Sheffield, United Kingdom, ni ọjọ Ojoru, àwọn ọmọ Nàìjíríà, Asake ati Limoblaze gba àmì ẹ̀yẹ tó ga.
Asake gba àmì ẹyẹ ti wọn pé ni – “Best African act” . Akọrin ìgbàgbọ́, Limoblaze náà gba àmì ẹyẹ ti wọn pé ni ” best gospel act.”.
Asake wa ni sàwáwù ogbontarigi akorin ọmọ Nàìjíríà bíi Adekunle Gold, Davido, Rema, Ayra Starr, Burna Boy, Wizkid, àti Rema. Bakanna pelu Tyla, ọmọ ilẹ̀ South African , Libianca, ti Cameroonian-American ati osere eSwatini, Uncle Waffles.
Àmì ẹ̀yẹ MOBO jẹ́ ti ọdọọdún ti ilẹ̀ gẹẹsi fún àwọn lami laaka Olórin lati buyi fún wọn fún aseyege wọn ninu orin tó ni Ibere pẹ̀pẹ̀ adulawo nínú bii :hop, grime, UK Drill, R&B, soul, reggae, jazz, gospel, ati orin ile Afirika.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san