Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Yóò Dá Ilé-ẹ̀kọ́ Ìṣègùn Àwọn Ológun Sílẹ̀ ‎

205

Ìjọba Nàìjíríà ti kéde ètò láti dá ilé-ẹ̀kọ́ ìṣègùn àti sáyẹ́ǹsì ìlera (Armed Forces College Of Medicine and Health Sciences AFCOM&HS) sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan nínú àwọn ìsapá láti mú kí ìtọ́jú ìlera lágbára síi láàrín àwọn ológun àti láti mú kí agbára ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn Nàìjíríà gbòòrò síi.

‎Èyí ni a sọ nínú ìkéde kan tí Olùdarí Ìròyìn àti Àjọṣepọ̀ Gbogbogbòò ní Ilé-iṣẹ́ Ẹ̀kọ́ ti Àpapọ̀, Folasade Boriowo, fi sílẹ̀.

‎Ní aṣojú Mínísítà fún Ẹ̀kọ́, Dókítà Tunji Alausa, Boriowo ṣe ìkéde náà nígbà ìpàdé gíga pẹ̀lú Mínísítà fún Ààbò, Ọgágun Christopher Musa tó ti fẹ̀yìntì, àti àwọn alẹnu-lọrọ pàtàkì. Àwọn mìíràn tí wọ́n tún wà níbi ìpàdé náà ni Mínísítà fún Ẹ̀kọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Suwaiba Ahmad, àti Mínísítà fún Ààbò, Dókítà Bello Matawalle.

‎Gẹ́gẹ́ bí Alausa ti sọ, ilé-ẹ̀kọ́ náà bá ètò àtúnṣe gbogbogbòò ti Ìjọba Àpapọ̀ mu, pàápàá jùlọ àwọn ètò tí a gbé kalẹ̀ láti mú kí ẹ̀kọ́ Sáyẹ́ǹsì, Ìmọ̀-ẹ̀rọ, Ìmọ̀-ìṣirò àti Ìmọ̀-ẹ̀rọ Ìṣègùn lágbára síi.

Comments are closed.

button