Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Se Ìfilọ́lẹ̀ Iṣẹ́ Àkànṣe Láti Mú Ààbò Oúnjẹ Dára Síi

197

 

Nàìjíríà ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ Iṣẹ́ Àkànṣe onígbáméjì láti mú ààbò oúnjẹ lágbára àti láti kọ́ àwọn ètò oúnjẹ amóunjẹpọ̀si nípasẹ̀ àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ àti àwọn ìníyelórí iṣẹ́ àgbẹ̀ tí o n tẹẹ síwájú a mú sunwọ̀n síi.

Ìgbésẹ̀ náà ṣe akanṣe àjọṣepọ̀ láàárín orílẹ-èdè Nàìjíríà àti European Union, pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè ọmọ ẹgbẹ́ míràn bíi Czech Republic, Austria, àti Latvia, láti ṣe àtìlẹ́yìn fún ètò ìṣẹ̀dá oko tí ó le dara àti tí ó le pẹ́.

Iṣẹ́ náà ní èrò láti mú kí iṣẹ́ àgbẹ̀ tí ó ní ìmọ̀ nípa ojú ọjọ́ pọ̀ sí i, láti mú kí agbára ilé-iṣẹ́ pọ̀ sí i, àti láti so àwọn ìlànà iṣẹ́ àgbẹ̀ Nàìjíríà pọ̀ mọ́ àwọn ìlànà tí ó dára jùlọ kárí ayé.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ náà ní Abuja, Mínísítà fún iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ààbò oúnjẹ, Sẹ́nétọ̀ Abubakar Kyari, sọ pé ètò náà yóò mú kí àwọn ìsapá láti mú kí ètò oúnjẹ tó wà fún ìgbà pípẹ́ lágbára sí i ní gbogbo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

 

Temitọ́pè Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button