Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Fi Ọwọ́ Sí Yíyan Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Mẹsan Fún Ìgbákejì Rẹ̀.

0 270

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde tí bu ọwọ́ lu yíyan Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ mẹsan fún igbákejì rẹ̀, Bayọ Lawal.

Bákan náà ní Makinde tún yan Adetola Adedibu gẹ́gẹ́ bíi Olùrànlọ́wọ́ Pàtàkì ti yóò máa sójú rẹ̀ (Special Assistant Liaison Office) ní ìlú Abuja.

Orúkọ àwọn Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ mẹsan náà gẹ́gẹ́ bíi lẹ́tà tí Olórí Oṣiṣẹ, Otunba Segun Ogunwuyi fi síta ni wọnyii:
1. Ajagbe Yusuf Olatunji: Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Òṣèlú (SA Political)

2. Sakariyah Kunle Sanni: Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Ìṣàkóso (SA Administration)

3. Hassan Ajibade: Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Òfin (SA Legal)

4. Omoetan Omolere: Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ Ìwé Ìròyìn (SA Print Media)

5. Badmus Adesola: Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Abẹ́lé (SA Domestic)

6. Oyedeji Ahmed: Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Àwùjọ (SA Public Affairs)

7. Alhaji Nasiru Ayinde: Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lórí Iṣẹ Àkànṣe (SA Projects)

8. Ajibade Waheed Ademola: Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lórí Ìròyìn orí ẹrọ Ayélujára (SA Media Online)

9. Mutalib Adewale: Olùrànlọ́wọ́ Ara Ẹni (Personal Assistant)

Nígbà tí o n kí gbogbo àwọn èèyàn náà kú oríire, Gómìnà gba wọn níyànjú láti rí ìyànsípò náà gẹ́gẹ́ bíi ìpè láti ṣiṣẹ.

O wa rot wọn láti ṣe iṣẹ wọn pẹlu òtítọ́ inú.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button