Take a fresh look at your lifestyle.

Kò Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Fi Ipò Aṣojú Orílẹ̀ Èdè Fún Àwọn Olóṣèlú – Ambassador Bolaji Akinremi

80

Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa ọ̀rọ̀ tó níí ṣe pẹ̀lú ilẹ̀ òkèèrè, Ambassador Bolaji Akinremi ti sọ di mímọ̀ pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fún àwọn olóṣèlú ní ipò Aṣojú Orílẹ̀ èdè nítorí iṣẹ́ náà jẹ́ iṣẹ́ ìfẹ̀mí wéwu látàrí ìpèníjà tó rọ̀ mọ́ ọ.

Amb. Akinremi, ẹni tó ti fi ọdún Márùndínlógójì (35) ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni ẹka iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó n rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè (Ministry of Foreign Affairs) ló ti gba ìjọba àti gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn níyànjú láti rí dájú pé wọ́n fi ìka tó tọ́ ro imú nípa fífi àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ sí ipò Aṣojú Orílẹ̀ èdè.

Akinremi ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí níbi àpéjọ àwẹ̀jẹ-wẹ̀mu eléyìí tí Àgbáríjọ Akẹ́kọ̀ọ́ gbọye jáde (Alumni) nínú ìmọ̀ “International Relations” láti ilé ẹ̀kọ́ gíga Fafiti Obafemi Awolowo (OAU), ni Ilé Ifẹ̀, Ìpínlẹ̀ Ọsun ṣe àkojọpọ̀ rẹ̀ láti mọ rírì Amb. Bolaji Akinremi tó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàrin wọn láti jẹ́ Aṣojú Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ilẹ̀ òkèèrè.

Akinremi, ẹni tó mẹnu ba díẹ̀ lára ìrírí rẹ̀ lẹnu iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Aṣojú ṣàlàyé báyìí “Àwọn àkókò ìpèníjà wà nínú ìrìn àjò yìí to nira gan an. Iṣẹ́ ìjọba òkè òkun (foreign service) jẹ́ iṣẹ́ tí ó le gan an, nítorí náà nígbà tí ẹ bá fẹ́yìntì, ó yẹ kí ẹ máa dúpẹ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní ló wà láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, mo sì dúpẹ́ pé mi ò fà sẹ́yìn kúrò nínú wọn.”

Síwájú sii, Amb. Akinremi mẹ́nu bá àsìkò tó gba àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kúrò ni Orilẹ èdè Ukraine, Akinremi ní: “Mo mọ̀ dájú pé ìgbésẹ láti gba àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, pàápàá jùlọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kúrò ní orílẹ̀ èdè Ukraine jẹ́ ohun tó léwu ṣùgbọ́n mo rántí àwọn ọmọ kékeré wọ̀n yẹn tí mo to ìwé ìrìnnà (visa) wọn gẹ́gẹ́ bí Olórí aṣojú orílẹ̀ èdè tó ń bójú tó ìrìnàjò, ìwé ìrìnnà, àti ìtọ́jú ará ilẹ̀ òkèèrè (Division Consular Leader). Mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó jẹ́ Ààrẹ lásìkò náà, olóògbé Mùhámádù Buhari to yọnda owó fun ọkọ̀ òfurufú tó gbé wọn kúrò ní Ukraine”

Bákan náà, Ó ke sí Ìjọba láti rí i dájú pé wọ́n ń bójú tó ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè míràn dáadáa, nígbà tí fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ aṣojú (career diplomats) nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti fi iṣẹ́ rán lọ ilẹ̀ òkèèrè, kìí ṣe olóṣèlú ti kò mọ ohun kankan nípa iṣẹ́ aṣoju orilẹ èdè.

Ṣáájú ní Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja, Arusa I ti fi Akinremi ṣe ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olúbàdàn fún Ètò Ọrọ̀ Ajé àti Okòwò (Olubadan Economic and Investment Committee), nínú èyí tí Tajudeen Arẹmu, tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Olórí Òṣìṣẹ́ Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Bobajiro ilẹ̀ Ìbàdàn ti fi àsìkò náà fi ìwé ìyànsípò náà fún Amb. Akinremi.

Bákan náà, nígbà tó n sọ̀rọ̀ nípa Akinremi, Ayaba Mutiat Ladoja fi Akinremi wé onínú ire ènìyàn, ẹni tó n ṣe àfihàn ohun ti wọn mọ ilẹ̀ Ìbàdàn sí, tíi ṣe wiwà ìgbéga ẹlòmíràn.

Ayaba Ladoja wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, iye ọdún tí Akinremi ló lẹ́nu iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Aṣojú Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti mú ìgbéga dé bá ìlú Ìbàdàn àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀.

Lára àwọn tó peju síbi àpéjọ náà ni: Ayaba Mutiat Ladoja; Ọjọgbọn Soji Adejumo; àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Aṣojú Orílẹ̀ èdè (Diplomatic Corps); àwọn ọ̀rẹ́; àwọn alábàṣiṣẹ́pọ̀; àwọn akẹgbẹ́ ni ilé ẹ̀kọ́; ìdílé àti ojúlùmọ̀.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button