Take a fresh look at your lifestyle.

Ìwé Òfin Iná Mọ̀nàmọ́ná 2023: Nàìjíríà Yóò Ló Ànfààní Àgbàrá Ẹkùn Kọ́ọ̀kàn – Mínísítà

0 321

Nínú ìgbìyànjú látí pèsè Iná Mọ̀nàmọ́ná fún àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè yìí, ìjọba Nàìjíríà tí ṣètò látí ṣàwarí àgbàrá àgbègbè kọ́ọ̀kàn pẹ̀lú èrò látí sọ ẹ̀ka náà dì ọtún.

Mínísítà fún ètò Iná mọ̀nàmọ́ná tí Nàìjíríà, Adebayo Adelabu, ṣé àfihàn èyí ní Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ọlọdọọdún ìkẹta irú rẹ̀, tí ‘Power Correspondents’ Association of Nigeria (PCAN)’ ṣètò rẹ̀, pẹ̀lú àkòrí “Resolving Nigeria’s Power Crisis: Implication of the Electricity Act, 2023”.

Mínísítà náà ṣàpèjúwe kókó-ọ̀rọ̀ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí kó bójú mú, pẹ̀lú akitiyan Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu látí pèsè iná mọ̀nàmọ́ná káàkiri orílẹ̀-èdè yìí pẹ̀lú ìfilọ́lẹ̀ òfin iná mọ̀nàmọ́ná tí ọdún 2023.

Tá bá rántí pé ní ọjọ́ kẹsán Oṣù Kẹfà, ọdún 2023, ní Ààrẹ Tinubu fọwọ́sí ìwé-àṣẹ iná mọ̀nàmọ́ná èyí tó sọ ọ di òfin pé àwọn ìpínlẹ̀, àwọn ilé-iṣẹ́, àti àwọn ẹní kọ́ọ̀kàn látí ṣé iná àtí pínpín iná.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button