Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Nasarawa Yoo Wádìí Bí Wọ́n Ṣe Se Ètò Ìrẹmọlẹ́kún Kúmọkùmọ

0 232

 

Ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin Nasarawa ti yan kọmití ẹlẹ́ni méje láti tanná wádìí ètò ìrọ̀rùn ìrẹmọlẹ́kún tí ìjọba se fún àwọn mẹ̀kúnnù, òtòsì tí àwọn kan gbé gba ọ̀nà ibòmíràn lọ.

Gbogbo ilé fi ẹnu kò pé àwọn tó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ láabi náà ni ìjọba yóò fi ìyà tó tọ́ sí wọn jẹ wọ́n lábẹ́ òfin.

Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, ọ̀gbẹ́ni Balarabe Abdullahi ló yan àwọn Kọmití náà labẹ́ òfin ẹ̀tọ́ ará ìlú tí Ọnarébù Musa Ibrahim Abubakar gbé jáde (ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP, Gúsù Doma) ní àkókò ìpàdé ní ìlú Lafia.

Ọnarébù Musa pè fún ìyá tó tọ́ fún àwọn tó gbé owó ìrànwọ́ fún àwọn mẹ̀kúnnù gba ọ̀nà ibòmíràn lọ kí ó leè jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn ènìyàn míràn tó gbèrò láti wu irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button