Take a fresh look at your lifestyle.

Ile Aṣofin Eko ti fọwọ si Ayẹwe-owo-wo agba ti Gomina ṣẹṣẹ yan

0 331

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti fọwọ si ọgbẹni Salami Sikiru gẹgẹ bi Ayẹwe-owo-wo Agba Ipinle Eko, eni ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinlẹ Eko yan fun ipo naa.
Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru ọbasa lo kede if Ile Igbimọ wosi yii, leyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ ti fi ohun wọn gẹgẹ bi ibo ṣatileyin fun un nibi ipade ijiroro ile naa lọjọ Iṣẹgun Tuesday.
Ọgbeni Salami ti koko fara han fun ayẹwo niwaju ile naa.
Bakan naa ni Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ka Abadofin ṣiṣe agbekalẹ Ajọ to n mojuto Igbogun ti Iwa Ibajẹ ati ṣiṣe otitọ lenu iṣẹ ti ọdun 2022, ni igba keji ni gbagede Ile Igbimọ Aṣofin naa. Lẹyin eyi ni Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru ọbasa fa agbeyẹwo Abadofin naa ni kikun le Igbimọ to n moju to ẹka eto idajọ ninu ile lowo.
Nigba ti won n sagbeyewo Abadofin naa ninu ile, Aṣofin Gbolahan Yisawu ati Aṣofin Victor Akande gboriyin fun awọn akẹgbẹ wọn bi wọn ṣe gbaruku ti Abadofin naa.
Igbimọ to n mojuto ẹka eto idajọ naa ni ireti wa pe wọn yoo jabọ lori Abadofin naa laarin ọsẹ kan si asiko yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button