Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó gbé òṣùbà o-káre ọmo ̣ọ̀dọ̀ rere fún Àar̀ẹ Tinubu fún ọgọ́rùn-ún ọjọ́ rẹ̀ lórí àlééfà

0 235

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ki Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti orilẹ-ede Naijiria ku oriire ọgọrun ọjọ lori aleefa, wọn gboriyin fun iṣẹ takuntakun rẹ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin Eko woye pe, akitiyan Aarẹ ko ṣaifara han ninu ọrọ-aje pẹlu bi ọrọ owo ori epo-rọbi ti wọn yọ ṣe mi ilu titi.

Wọn tun rọ ijọba lati pin ohun elo iranwọ iṣadinku ipalara owo ori epo rọbi ti wọn yọ naa ni dọgbadọgba laisi ojuṣaaju.

Ạṣofin Fẹmi Saheed ti o sọrọ yii ni asiko Ọrọ Pajawiri ninu ijiroro Ile Aṣofin naa,  woye pe, pẹlu gbogbo iṣẹ akin ti Aarẹ Tinubu ti ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii, o tọ ki wọn gboṣuba o-kare fun un. Nigba ti o n mẹnu ba awọn aṣeyọri Aarẹ, o mẹnu ba erongba ijọba rẹ lati ṣe idasilẹ ile-iṣẹ ipese afẹfẹ gaasi mẹtadinlọgọta ti wọn fẹ da silẹ, iyẹn ‘Compressed Natural Gas, ti yoo le ṣadinku atubọtan ọwọn gogo epo-rọbi. O ni:

“Bakan naa ni Aarẹ Tinubu ti ṣi ọpọlọpọ anfani silẹ lati fun awọn olokoowo lati ilẹ okeere laaye lati wa dokoowo ni orilẹ-ede yii. Gbogbo eleyii lo yẹ ki a fi gboṣuba sadankata fun aarẹ.”

Aṣofin Akinsanya Nureni ti oun naa gbe sẹyin awọn akẹgbẹ lati yin Aarẹ, rọ awọn to wa nidii ohun elo iranwọ iṣadinku ipalara owo ori epo-rọbi yii ri i daju pe, o de gbogbo ibi to yẹ ki o de.

Aṣofin Adewale Temitọpẹ gboriyin fun Aarẹ Tinubu paapaa fun igberu to ba eto irinna ọkọ ati erongba lati fi owo kun owo oṣu awọn oṣiṣẹ. O ni:

“Bakan naa ni mo ki Aarẹ fun ipo Alaga ajọ ECOWAS ti wọn yan wọn si bayii.”

Aṣofin Olumoh Lukman dupẹ lọwọ Ọlọrun fun olori to n gbọ ẹdun ọkan awọn ara ilu bi Aarẹ Tinubu ti O fun wọn. O ni:

“Aarẹ jẹ ẹni ti o n tẹle ọrọ rẹ, o ti fi àwọn ọdọ́ sinu igbimọ alakoso rẹ ati awọn ipo miiran bayii.”

Igbakeji Ọmọ ẹgbẹ Oṣelu to pọ ju lọ ninu Ile Aṣofin naa, Aṣofin Adedamọla Kasunmu fi mulẹ pe, lati igba ti wọn ti bura fun Aarẹ Tinubu ni orilẹ-ede yii ti n je igbadun ayipada rere.

Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa wa dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin naa ti wọn mọ riri iṣẹ takuntakun Aarẹ, o ni:

“Yinni-yin-ni kẹni o ṣe omiran, Aarẹ ti mu ọpọ ayipada rere ba awọn ẹka ọrọ-aje lorilẹ-ede yii. Awọn ara ilu ti n jẹ anfani aṣeyọri Aarẹ Tinubu bayii. Bakan naa ki a ri i daju pe, awọn to nilo ohun elo iranwọ  iṣadinku ipalara owo ori-epo rọbi yii lo de ọdọ wọn, boya ni ti ẹka iṣẹ-agbẹ, eto irinna ọkọ, eto ilera ati ẹka eto ẹkọ.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button