Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣojú ti pe àwọn olórí àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò tí ó yẹ lórí ìkọlù pápá ọkọ̀ òfurufú ìlu Kàdúná àti ọkọ̀ ojú irin Kàdúná sí Àbújá tí ó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.
Eyi tẹle ifohunṣọkan igbero pataki orilẹ-ede ti ọmọ ẹgbẹ kan lati Ipinlẹ Enugu, Nnolim Nnaji ṣonigbọwọ rẹ nibi apejọ.
Aṣofin naa kẹdun lori ikọlu papa ọkọ ofurufu Kaduna naa ti o fa iku oluṣọ aabo ti ile-iṣẹ iṣakoso oju-ofurufu Naijiria NAMA.
Aṣofin naa tẹnumọ iwulo lati pese idaabobo to koju osunwọn ni gbogbo awọn papa ọkọ ofurufu,o fifi kun pe ti wọn ko ba gbe igbesẹ toba yẹ lori ikọlu naa, o le tan si awọn apa ibomiiran ni orilẹ-ede.
Leave a Reply