Ìjọba Nàìjíríà tí pinnu láti yanjú àwọn ìpèníjà tí ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ ti ìyè owó oúnjẹ tí ń pọ̀ sí i, ìnira ọrọ̀ ajé, àti ìpèníjà ààbò tí ń kan àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Mínísítà fún Ìròyìn àti Alaye tí Orílẹ̀-èdè, Mohammed Idris Malagi sọ èyí làkókò ìpàdé gbogboògbò ọdọọdún tí ‘Nigeria Institute of Public Relations’ Ìpínlẹ̀ Niger.

Aṣojú Mínísítà náà, Olùdarí Gbogbogbò tí Ilé Akéde Nàìjíríà (Voice of Nigeria VON), Malam Jibrin Baba Ndace sọ pé, Mínísítà náà jẹ́wọ ọwọn-gogo ìyè owó tí àwọn oúnjẹ àtí àwọn ọjà pàtàkì mìíràn ní àwọn ọjà wá, o ṣé ìlérí pé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ́ ní Ìjọba tí ń gbé láti kojú ìpèníjà náà.