Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kaduna Dá Ilé Iṣẹ́ Ìṣelọ́jọ̀ Àti Ìkórè Ohun Ọ̀gbìn Sílẹ̀

0 434

Lójúnà àti dènà sísòfò nǹkan oko fún àwọn àgbẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kaduna, ìjọba ìpínlẹ̀ náà, lábẹ́ẹ Kaduna State Agro- Enhancement and Livelihood Impovement Support (APPEALS) ti setán láti dá ilé isẹ́ mẹ́ẹ̀dógún sílẹ̀ fún ìselọ́jọ̀  àti ìkórè nǹkan oko fun lílò ọjọ́ iwájú àti láti mú ìgbòòrò bá ètò ọ̀gbìn.

 

Alakoso ètò náà, Mohammad Basir Amin rí sísòfò ohun ọ̀gbìn gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà kan gbòógì tí ó ń mú ìfàsẹ́yìn bá ètò ọ̀gbìn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àtipé gbogbo ọ̀nà ni àwọn yóò wá láti wá ojútùú sí ìsòro náà.

 

Amin tún sàlàyé pé, ètò náà yóò dá ìpèsè isé sílẹ̀ tí yóò sì mú ìgbòòrò bá ọrọ̀ ajé wa. Ó gbé oríyìn fún ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna fún àmúgbòòrò ètò ọ̀gbìn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button