Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò Gbogbogbò 2023: Ààrẹ Buhari Bálẹ̀ Sí Ìpínlẹ̀ Katsina

1 529

Ààrẹ Muhammadu Buhari tí dé sí Ìpínlẹ̀ Katsina látí kópa nínú ìdìbò Ààrẹ àtí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà tí Orílẹ̀-èdè tí Ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Olórí Orílẹ̀-èdè yìí tó balẹ̀ sí Pápákọ̀ Òfurufú Umaru Yar’Adua International Airport, Katsina ní àgó Márùn ùn kú ogún ìṣẹ́jú (16:40 GMT), tí Gómìnà Aminu Masari àtí àwọn aṣojú ìjọ̀ba Ìpínlẹ̀ náà kí káàbọ̀.

Lára àwọn tó tẹ̀lé Ààrẹ ní ìyàwó rẹ̀ Aisha, ẹbí àtí àwọn amugba lẹgbẹ rẹ̀.

Ní kété lẹyìn tó dé, Ààrẹ ṣé àbẹwò àwọn ẹṣọ́ awọn ọmọ ogún Orílẹ̀ (Nigeria Army) àtí òfurufú (Air Force) tí Ìpínlẹ̀ náà tó bú ọlá fún.
Lẹyìn náà ní wọ́n tẹ̀síwájú lọ́ sílùú Daura, níbí tí yóò tí dìbo rẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Tún kà nípa:Ìdìbò Ààrẹ Àti Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣojú-Ṣòfin: Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Kéde Kí Òṣìṣẹ́ Ìjọba Ṣíwọ́ Iṣẹ́ Ní Agogo Méjìlá Ọsan Ọjọ́ Ẹtì

Ní báyìí, ètò tí tó ní ìpínlẹ̀ náà fún ìdìbò Àbámẹ́ta, nítorí ààbò tó péye tí wá ní gbogbo àwọn àgbègbè tí Ìpínlẹ̀ náà.

Ní ọsàn Ọjọ́bọ̀, ní àgó méjì kọjá iṣẹju mẹ̀ẹ́dọ́gbọ́n (14:25 GMT) ní ọkọ Òfurufú kàn tí kó àwọn òun èlò ìdìbò wá sí ìpínlẹ̀ náà, èyí tí wọ́n gbé lẹsẹkẹsẹ lọ́ sí ilé ifowopamọ àpapọ̀ Central Bank of Nigeria ẹka tí Katsina.

Lekan Orenuga

One response to “Ìdìbò Gbogbogbò 2023: Ààrẹ Buhari Bálẹ̀ Sí Ìpínlẹ̀ Katsina”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button