Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Soludo Se Ìrànlọ́wọ́ Fún Àwọn Ọ̀dọ́ Ìpínlẹ̀ Anambra

0 201

Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra, Ọ̀jọ̀gbọ́n Chukwuma Charles Soludo ti pèsè ìrànlọ́wọ́ owó fún àwọn ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́jáde tí kò dín ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún fún ìpele alákọ̀kọ́ọ́ tí ìrètí sì wà pé ìpele ẹlẹ́ẹ̀kejì yóò mú ìrànlọ́wọ́ bá ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn ọ̀dọ ìpínlẹ̀ náà.

 

Gómìnà se àgbékalẹ̀ ìpinu ìsèjọba rẹ̀ láti mú ìgbéga bá ìpínlẹ̀ náà pẹ̀lú pípèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ, èyí tí yóò mú ìgbòòrò bá ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà.

 

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ náà, gómìnà sàdéhùn pé òun yóò pèsè owó fún àmúlò àwọn ọ̀dọ́ láti ara ẹgbẹ́ àjùmọ̀ṣe tí wọ́n ti dá sílẹ̀ èyí tí yóò fún wọn ní ànfààní ẹ̀yáwó tí ó tó mílíọ̀nù márùn-ún fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button