Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀ka Ti Ààrẹ, Àjọ CYMS Gbé Îgbèésẹ̀ Láti Mú Ìdàgbàsókè Ba Ere-idaraya Ní Ẹsẹ̀kùkú

60

 

Gẹ́gẹ́ bí apá kan ọ̀ná láti mú kí ìdàgbàsókè bá eré-idaraya tó wà ní ìpele gbogbogbòò lágbára síi ní Nàìjíríà, Olùrànlọ́wọ́ Pàtàkì Àgbà fún Ààrẹ lórí Ìdàgbàsókè Ere-idaraya ní ẹsẹ̀ kùkú, Adebayo Adeyinka, gba àwọn aṣojú láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ àjọ Committee of Youths on Mobilisation and Sensitisation (CYMS) ní alejo ní ọ́fíìsì rẹ̀ ní Abuja, olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìpàdé náà dojúkọ àwọn agbègbè ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó ṣeéṣe láti mú kí eré-idaraya Nàìjíríà tún padà bọ sípò nípasẹ̀ àwárí ẹ̀bùn, àtúnṣe ètò ìṣiṣẹ́ àti àtúnṣe ìlànà.

Olùdarí Àgbà fún ẹgbẹ́ CYMS, Obinna Nwaka, ló ṣáájú àwọn aṣojú CYMS, ẹni tí Olùdarí Àjọ àti Ìṣíṣẹ́ fún ẹgbẹ́ náà, Kelechi Ugwumba, jọ kọ̀wọ́ rìn.

Nígbà ìjíròrò náà, àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì tẹnu mọ́ pàtàkì ti ṣíṣe àfikún eré-idaraya pẹ̀lú àwọn ètò agbára àwọn ọ̀dọ́ àti ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, wọ́n sì kíyèsí pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ṣì ṣe pàtàkì láti kọ́ ẹ̀ka eré-idaraya tó lè dúró ṣinṣin ní orílẹ̀-èdè yii.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nígbà ìbẹ̀wò náà, Nwaka gbóríyìn fún olùrànlọ́wọ́ ààrẹ fún ìgbalejò tó dára, ó sì gbóríyìn fún ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí ìdàgbàsókè eré-ìdárayá ìpele kékeré, ní ìbámu pẹ̀lú ètò isọdọtun -Renewed Hope ti Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button