Olùdarí Ilé Asòfin Èkó Ti Rọ Àwọn Ìjọba Ìpínlẹ̀ Láti Gbàrùkù Ti Àwọn Isẹ́ Ìdàgbàsókè ìlú Tí Aya Ààrẹ Ń Se
Olùdarí Ilé Ìgbìmò Asòfin Ìpínlè Èkó, Asòfin Mudashiru Obasá ti ro àwon ìjoba Ìpínlè káàkiri orílè-èdè Nàìjíríà láti gbàrùkù ti àwon isé ìrànlówó ìlú tí Aya Ààre, Asòfin Olúrèmí Tinubu n se. Ó sàpèjúwe Ètò Èròngbà Ìrètí Ìsodòtun re bí èyí tí ó fi n tún ìgbésí ayé àwon obìnrin àti òdó tó kù díè káàtó se.
Nígbà tí ó n bá àwon oníròyìn Ilé-isé Ààre yìí sòrò léyìn tí ó se àbèwò sí Aya Ààre náà lójó Etì (Friday) Asòfin Obasá so pé:
“Àwon ìjoba Ìpínlè ní láti se àmúlò àwon ànfàní tí Aya Ààre n pèsè nínú Èròngbà Ìrètí Ìsodòtun Ìjoba yìí láti fesè ìdàgbàsókè múlè fún àwon ènìyàn wa.”
Olùdarí Ilé Asòfin Èkó náà so pé, àwon Ètò tí Asòfin Tinubu n sagbáterù rè yìí ti n so èso rere ní àwon èka pàtàkì bí èto èkó, ètò ìlera àti èka ìrónilágbára orò-ajé.
Ó ní bí wón bá lè fowósowópò láti àwon ìpele ìjoba tó kù, àwon ètò yìí yóò ní ipa tó pò.
Nígbà tí ó n gbóríyìn fún ìfojúsùn àti akitiyan Aya Ààre yìí, Asòfin Obasá sàpèjúwe akitiyan rè yìí gégé bí èyí tó wá lásìkò tó dára pàápàá fún àwon tó kù díè káàtó fún. Èyí tí ó n se àdínkù ìsé àti òsì fún àwon ará ìlú.
Asòfin Obasá sàlàyé pé, àbèwò òun náà kì í se láti jíròrò lórí òrò ìdàgbàsókè ìlú nìkan, sùgbón láti tún kí Asòfin Tinubu fún ti ààwè Ramadan àti ààwè àwon omoléyìn Krístì tó bó sí àsìkò kan náà nínú odún yìí.
Ètò Èròngbà Ìrètí Ìsodòtun tí Asòfin Olúrèmí Tinubu fi lólè ti so èso rere pàápàá láti wá ojútùú sí àwon ìsòro tó n kojú àwon obìnrin àti àwon òdó. Bèrè láti orí ìkóni-nísé àti ìpèsè owó ìrànlówó dé orí èka ètò Ìlera àti ètò èkó, tí òpò ènìyàn sì n gbóríyìn fún akitiyan yìí káàkiri orílè-èdè Nàìjíríà.
Lánre Lágada-Àbáyòmí.