Ẹgbẹ́ kan lábẹ́ àkóso àjọ Mai Dunama Sickle Cell Foundation (MAISCEF) ti mú kí àwọn ìsapá wọn pọ̀ sí i láti mú kí ìmọ̀ nípa àrùn Sickle cell pọ̀ sí i, wọ́n ń rọ ìjọba láti mú kí ìmọ̀ nípa àrùn náà pọ̀ sí i, kí wọ́n sì ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn ètò lórí àìsàn náà.
Ẹgbẹ́ náà sọ èyí di mímọ̀ níbi ti wọ́n ti ń pín àwọn ohun iwulo àti òògùn fún ètò Ramadan fún àwọn aláìlera.
Olùdásílẹ̀ àti Olórí Àgbà, Rabi Mai Dunama, sọ pé ètò náà tẹnu mọ́ ìdúróṣinṣin àjọ náà láti kọ́ gbogbo ènìyàn nípa àrùn Sickle cell àti láti ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn tí ó ní àrùn náà, pàápàá jùlọ àwọn tí kò ní àǹfààní.
Ó ṣe àkíyèsí pé ètò Ramadan tí a ṣe àkójọ rẹ̀ jẹ́ ara àwọn ìsapá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ láti ṣèàtìlẹ́yìn fún àwọn aláìní ní àsìkò ààwẹ̀ nígbà tí ó ń gbé ìfúnni onínúure lárugẹ.
Arabinrin Maidunama ṣàlàyé pé “àjọ náà ń kópa nínú àwọn ijadelọ àwùjọ àti ilé ìwé, ìmọ̀ràn ṣáájú ìgbéyàwó, àti ìdánwò ẹ̀yà ara,Jẹ́nótáìpù ọ̀fẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ láti gbé ìpinnu ìgbéyàwó lárugẹ àti láti dín ìtànkálẹ̀ àrùn náà kù.”

Ó tún ké sí ìjọba àti àwọn alenulọ́rọ̀ láti ṣe àgbékalẹ̀ àti láti fi àwọn ìlànà tí yóò sọ ìdánwò ẹ̀yà Jẹ́nótáìpù, genotype di dandan kí a tó ṣe ìgbéyàwó, ó sì tún sọ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ìsìn àti àṣà ṣe pàtàkì láti dín ìbísí àrùn náà kù.
Àjọ MAISCEF ń tẹ̀síwájú láti fẹ̀ sí i nípa ẹ̀kọ́, ìtìlẹ́yìn ìlera, àti àwọn ìdánilójú tí ó dá lórí àwùjọ káàkiri orílẹ̀-èdè yìí.
Temitọ́pè Òbísẹ̀san