Àyè Wà Fún Àwọn Olùdókoòwò Ilẹ̀ Òkèèrè Láti Kópa Nínú Ètò Ọrọ̀ Ajé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà- Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin
Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin, Godswill Akpabio ti fi àrídájú ànfààní tí ó wà fún àwọn olùdókoòwò ilẹ̀ òkèèrè léde ní àyájọ́ Ọjọ́bọ̀, láti kópa nínú ètò ọrọ̀ ajé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Sẹ́nétọ̀ Akpabio sọ ọ̀rọ̀ náà ní ọ́ọ́fìsì rẹ̀ nígbà tí ó gba àlejò ilé iṣẹ́ (Jampur) èyí tí alákòso ilé iṣẹ́ náà Mohammed Shafiq, sojú.
Sẹ́nétọ̀ Akpabio sàpèjúwe ìgbésẹ̀ ìjọba àpapọ̀ láti ní ìpààrọ̀ owó ẹlẹ́nu kan gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó sàfihàn ààbò fún àwọn olùdókoòwò ilẹ̀ òkèèrè. Ó wá fi dáwọn lójú pe,́ ìjọba àpapọ̀ ti gbáradì láti dáàbò bo ìdókoòwò wọn.
Leave a Reply