Àwọn Ẹgbẹ́ Ọkùnrin àti Obìnrin eré sísá onígi gbígbà 4x100m orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gba àmì ẹ̀yẹ góòlù àti idẹ ní ọjọ́ kẹwa ìdíje eré àjọ commonwealth ni Birmingham, ọdún 2022 tó wáyé ni Pápá Alexander ni ojo Àìkú.
Àwọn ẹgbẹ́ Obìnrin fi Tobi Amusan sínú ẹgbẹ́ náà láàrin wákàtí méjì tó ṣẹ̀ jáwé olúborí nínú eré 100M Hurdles ti o sì tún já rekọọdu àjọ commonwealth, àwọn tó sá eré Obìnrin ni wọ̀nyí Tobi Amusan to bẹ̀rẹ̀ eré na, Favour Ofili, Rosemary Chukwuma àti Grace Nwokocha to pari eré náà.
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gba rekọodu Áfíríkà tuntun pelu iṣẹju àyáá 42.10s ti ẹgbẹ́ Obìnrin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kankan ò ti sá rí.

Nínú eré sísá onígi gbígbà 4x100m àwọn ọkùnrin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Udodi Onwuzuruike ni wón ní kó bere eré sísá dipo Seye Ogundele tó sá nìgbà igbaradi
Raymond Ekevwo bẹ̀rẹ̀ eré sísá náà, ti Onwuzuruike, Favour Ashe àti Akintola Alabi tí wọn si parí ni iṣẹju àyáá 38.85s pẹlu àmì ẹ̀yẹ idẹ.
Ọláyinká Akíntọ́lá.
Leave a Reply