Àwọn Agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Sẹ́gun Ikọ̀ Ti Iran Pẹlu Ayò Méjì Sí Oókan (2-1) Níbi Ìdíje Ọlọ́rẹ̀ẹ́-ṣọrẹ
Àwọn ikọ̀ Super Eagles ti orílẹ-èdè Nàìjíríà ṣẹ́gun ìkọ agbábọ́ọ̀lù orílẹ-èdè Iran pẹlu Ayò Méjì Sí Oókan (2-1) nínú ìdíje àkọ́kọ́ wọn nínú ìdíje orílẹ̀-èdè mẹ́rin ńí ọjó Etì ní pápá isere Mardan Titanic Sports Complex ní Antalya, Turkey.
Ògbóntàrigi agbabọ́ọ̀lù Moses Simon lo kọkọ yẹlé wò fún ìkọ Naijiria ní ìṣẹ́jú kẹfà ki ẹlẹsẹ ayò, Akor Adams to fi ekeji sì ni iṣẹju mokanlelaadota ní abala keji ere.
Ìkọ agbábọ́ọ̀lù Iran naa jẹ́wọ́ pé àwọn kò wa woran bí wón ṣe da ayò kan padà láti ẹsẹ agbábọ́ọ̀lù Mehdi Taremi ní iṣẹju métadinlaadọ̀rin ní ayò wà parí sí Méjì Sí Oókan (2-1) latari pé Ikọ̀ Nàìjíríà di ìlé wọn mu daradara kí wọn tó leè jagun mōlú.

Temitọ́pè Òbísẹ̀san