Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Pé Pérépéré Lẹ́yìn Tí Asájú Ikọ̀, Ndidi Dé.

137

 

Ibùdó Super Eagles ti Nàìjíríà ti kun fọfọ fún àwon agbábọ́ọ̀lù báyìí lẹ́yìn dídé Asájú Ikọ̀, Wilfred Ndidi sí ilẹ itura Bellis Deluxe ní Antalya, ṣáájú àwọn ìdíje ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ̀rẹ́ tó ń bọ̀ ní Turkey.

Olórí Olùkọ́ni Eric Chelle ti dárúkọ Asájú Ndidi, Alex Iwobi àti Ademola Lookman tẹ́lẹ̀ sinu ìkọ agbábọ́ọ̀lù eleni mẹ́tàlélógún fún àwọn ìdíje náà.

Ìṣẹ́jú ìkẹyìn ni Calvin Bassey yọ kúrò nínú àkójọ àwọn olùgbábọ́ọ̀lù tí a pè, latari ìpalára ẹ̀yìn tí ó ní nígbà tí ó ń gbá bọọlu fún Kílọ̀bù rẹ̀.

Wọ́n gbé àwọn ìdíje náà láti Amman sí Antalya nítorí rogbodiyan àti ìjà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Super Eagles yóò dojúkọ Iran ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, kí wọ́n tó gbájú mọ́ ikọ̀ Jordan ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta ní Antalya.

Àwọn olùgbábọ́ọ̀lù méjìlélógún wà ní ibùdó lọ́wọ́lọ́wọ́, wọ́n sì kópa ní kíkún nínú ìpalẹ̀mọ́ fún ifagagbaga tó ń bọ̀. Ẹgbẹ́ náà ṣe igbaradi àkọ́kọ́ rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn olùgbábọ́ọ̀lù tí ó wà níbẹ̀ tí wọ́n yóò kópa nínu idije náà.

Àkójọpọ̀ gbogbo àwọn agbábọ́ọ̀lù méjìlélógún tí ó wà ní àgọ́ náà niyii:

Fisayo Bashiru

Iwobi Alex

Emmanuel Oluwasegun

⁠Yira Sor

⁠Onuachu Paul

⁠Philip Otele

⁠Semi Ajayi

⁠Moses Simon

⁠Uzoho Francis

⁠Bruno Onyemaechi

⁠Bright Osayi

⁠Frank Onyeka

⁠Adebayo Adeleye

⁠Ademola Lookman

⁠Akor Adams

⁠Chidera Ejuke

⁠Raphael Onyedika

⁠Igoh Ogbu

⁠Maduka Okoye

⁠Samuel Chukwueze

⁠Zaidu Sanusi

Wilfred Ndidi (Aṣáájú).

 

 

 

 

Temitọ́pè Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button