Take a fresh look at your lifestyle.

Olórí Ẹgbẹ́ Òsèlú Alátakò Ní Orílẹ̀ Èdè Senegal Jẹ̀bi Ẹ̀sùn Ìbanilórúkọjẹ́

Olórí alátakò ní orílẹ̀ èdè Senegal, Ousmane Sonko ti jẹ̀bi ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ léyìí tí yóò sì fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì jura.   Wọ́n fi ẹ̀sùn ìbani-lórúkọjẹ́ kan Sonko lẹ́yìn ìgbà tí ó fi ẹ̀sùn síṣe owó…

Ọ̀gágun Ajagunfẹ̀yìntì Ọladipupọ Diya Dágbére Fáyé Lẹ́ni Ọdún Méjìdílọ́gọ́rin

Àwọn mọ̀lẹ́bí Ajagunfẹ̀yìntì Ọladipupọ Diya ti kéde pé akọni náà ti papòdà. Ìkéde náà fi yéwa pé Diya jáde láyé ní òwúrò kùtù Ọjọ́ Àìkú (Sunday) tí se ọjọ́ kẹrìndílọ́gbọ̀n osù kẹta ọdún 2023. …

Èsì Ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ogun Kò Jẹ́ Àtẹ́wọ́gbà- Ẹgbẹ́ Òsèlú PDP

Ẹgbẹ́ òsèlú PDP ti fi àáké kọ́rí tí ó sì tako  ìkéde tí àjọ INEC se lẹ́yìn ìdìbò tí ó wáyé ní ọjọ́ kejìdílógún osù kẹta ní ìpínlẹ̀ náà. Àjọ INEC kéde Ọ̀gbẹ́ni Dapọ Abiọdun ti ẹgbẹ́ òsèlú APC gẹ́gẹ́ bíi…

Lórí Ìgbẹ́jọ́ Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn: Àpapọ̀ Àwọn Ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Tí Ó Kéré…

Àpapọ̀ àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Asòfin èyí tí ó kéré jùlọ ní Ìlú Abuja ti kí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, Sẹ́nétọ̀ Ademọla Adeleke kú oríire nípa ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn èyí tí ó fi ìdí ìjáwé olúborí rẹ̀…

Ìròyìn Òfegé Ni Ìfiléde Tí Ó Sàfihàn Àkọlù Sí Ilé Ọ̀gá Àgbà Fún Àjọ INEC- Àjọ…

Àjọ Ọlọ́pàá ti ìpínlẹ̀ Bauchi ti fi ọwọ́ òsì da àhesọ ọ̀rọ̀ kan tí ó wà ní orí fán-án-rán ayélujára, eléyìí tí ó sàfihàn àkọlù láti ọwọ́ àwọn jàǹdùkú sí ilé Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu, ẹni tí ó jẹ́…
button