Take a fresh look at your lifestyle.

Àrọwà Wá Fún Àwọn Ìjọ Ọlọ́run Láti Ìpèsè Ohun Amáyédẹrùn

0 272

Àrọwà ti wá fún àwọn ìjọ ní ìlànà ẹ̀sìn láti má se kó àárẹ̀ níbi ìpèsè àwọn ohun amáyédẹrùn tí wọ́n ń dáwọ́ lé láti le è kojú àwọn ìsòro tí ó ń kojú àwùjọ wa.

 

Ìpèpè náà wáyé láti ẹnu akọ̀wé àgbà fún ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè ìgbèríko ní ìlú Abújá, Mallam Abubakar Ibrahim, ní òpin ọ̀sẹ̀ nígbà tí ó sí omi ẹ̀rọ èyí tí ìjọ Kírísítì, ẹka Kado pèsè fún àgbègbè náà.

 

Ó se àpèjúwe isẹ́ àkànse náà gẹ́gẹ́ bíi ohun ìwúrí, fífi ìfẹ́ hàn àti mímọ rírì ìsẹ̀mí ọmọ ènìyàn. Ó sì gba àwọn tí ó kù ní ìyànjú fún ìkọ́se dáada bẹ́ẹ̀.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button