Àjọ Standards Organisation of Nigeria (SON) ti fun Ile iṣẹ mẹ́rìnlélógójì ní ìwé èrí Mandatory Conformity Assessment Programme (MANCAP) moyege.
Wọ́n pín ìwé ẹ̀rí náà ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ ní ìlú Awka, Dókítà Ifeanyi Okeke tó jẹ ọ̀gá àgbà àjọ SON sọ pé àwọn ilé iṣẹ náà yege nípa Ipese àwọn nǹkan ti o dára abbl.
Ọgbẹni Chinedu Agafie tó sojú fún ọgbẹni Okeke, lu àwọn ilé iṣẹ tó n pèsè nǹkan náà ní ọ̀gọ ẹnu fún ipa rere tiwọn fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ aje orílẹ̀-èdè yìí.
Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ Sylflora Industries and Farms, Iyaafin Christiana Nwaele náà gbósùbà fún àjọ SON fun mímu ìgbòòrò bá àseyege ọjà ti wọn pèsè labẹ́lé nípasẹ̀ ṣíṣe atọ́nà rere fún wọn.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san