Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu buwọ́lu iye owó tó ju tíríọ́nù mẹ́ta lọ fún sísan gbèsè ẹ̀ka iná

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

31

Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti buwọ́lu iye owó tó ju tíríọ́nù mẹ́ta lọ gẹ́gẹ́ bí owó àsantán gbèsè ọlọ́jọ́ pípẹ́ , tó wànílẹ̀ fún ìṣàtúnṣe ní ẹ̀ka iná Nàìjíríà.
Alaye kan ti oludamọran pataki fun Aarẹ, Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga fi sita ni ọjọ Aiku, sọ pe Aarẹ buwọlu fun sisan gbese naa lasan tan nipasẹ Agbekalẹ Aarẹ fun Atunṣe Inawo Ẹka Ina.
Ọgbẹni Onanuga sọ pe igbesẹ sisan gbese yii waye lẹyin aṣekagba atunṣe lori gbese ajẹsilẹ ti o ti wa lọrun ẹka ina fun igba ti o ju ọdun mẹwaa lọ.
Wọn ti jẹ gbese ọlọjọ pipẹ yii silẹ laarin osu keji 2015 ati oṣu kẹta 2025.
O wa ṣalaye pe iṣewadi to waye nibayii wa fihan pe wọn ti fẹnuko lori sisan iye owó tó ju tíríọ́nù mẹ́ta yii gẹgẹ bii gbogbo rẹ ati asantan, ti eleyi si jasi pe iyaju rẹ han gbangba kedere, ti ko si ruju.
Ipese rẹ ti bẹrẹ pẹlu ẹrọ ipese ina mẹẹdogun ti wọn buwọlu ipinnu adehun ni iye to ju tiriọnu meji lọ. Ijọba apapọ si ti wa iye owo ookan-le ni- ẹẹdẹgbẹta biliọnu lati san gbese yii. Ninu iye owo yii wọn si ti san iye owo ẹẹta-le-logun-le-nigba biliọnu, ti sisan siwaju eyi toku si n bọ lẹyin.
Kini eleyii tumó si fun awón ómó Naijiria
Bi owo yii bati gunlẹ sibi ti n lọ, ina yoo maa wa. Pẹlu ẹrọ ti nṣeranlọwọ fun ina, igbẹkẹle ina yoo latunṣe.
Bi ẹka naa ba si ti fidi mulẹ, awọn idokowo yoo wọle wa, ọpọlọpọ anfaani iṣẹ, ati eto iṣẹ daradara naa yoo tẹlee.

Comments are closed.

button