Ààrẹ orílẹ̀ èdè Ghana, Nana Akufo-Addo ti gbé ìgbésẹ̀ akin lójúnà àti dóòlà ètò ọrọ̀ ajé tí ó da ẹnu kọlẹ̀, àti láti mú ìgbòòrò bá ìpèsè ohun èlò lábẹ́lé.
Ààrẹ Akufo-Addo fi léde pé ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọrun (30%) ni yóò bá ètò ìsúná owó, owó osù ààrẹ, igbákejì rẹ̀, àwọn mínísítà àti àwọn tí ó di ipò òsèlú mú.
Ó sàlàyé síwájú pé, àrùn covid-19 ati ogun tí ó n lọ lọ́wọ́ laàrin orílẹ̀ èdè Russia àti Ukraine ti mú ìfàsẹ́yìn bá ọrọ̀ ajé ilẹ̀ náà. Ní papàá jùlọ, níse ni gbèsè mu orílẹ̀ èdè náà dáru.
Ó tún sọ pé, orílẹ̀ èdè náà ti setán láti wá ọ̀nà àbáyọ láti ọwọ́ báńkì àgbáyé International Monetary Fund (IMF). Eléyìí yóò jẹ́ ìbéèrè ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínlógún (17th) irúu rẹ̀ sí ilé ìfowópamọ́ náà, lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè náà ti gba òmìnira ní ọdún 1957.
Leave a Reply