Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fi ìkíni ayọ̀ fún àwọn Mùsùlùmí ní orílẹ-èdè Nàìjíríà àti kárí ayé lórí ayẹyẹ Eid ul-Fitr, èyí tí ó ń ṣe àmì òpin oṣù Ramadan.
Nínú ìhìn rere ayọ̀ tí Agbẹnusọ Ààrẹ, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga fi ránṣẹ́ ní ọjọ ọjọ́rú, Ààrẹ Tinubu ké sí àwọn Mùsùlùmí láti tún ìdúróṣinṣin wọn sí orílẹ̀-èdè àti agbáyé ṣe.
Ó rọ̀ wọ́n láti gbé àwọn ìlànà ìfọkànsìn sì Ọlọrun, ìfọkànsìn, ìṣọ̀kan, àti ìyọ́nú tí a gbìn nígbà àsìkò ààwẹ̀ dúró.
Ààrẹ tẹnu mọ́ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ‘dúró ninu àwọn ìwà rere bíi àìní ìwà ìmọ tara-ẹni nikan, ìfaradà, inú rere, àti àánú lẹ́yìn oṣù mímọ́.’
“A ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan láti fà yọ láti inú àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ti Ramadan, pàápàá jùlọ ní àkókò bí èyí. A gbọ́dọ̀ máa tẹ̀lé àwọn ìwà rere ti ìfọkànsìn, àìní ìwà ìmọ tara-ẹni nikan, ìfaradà, inú rere àti àánú lẹ́yìn àsìkò yìí,” ó wí.
Ààrẹ Tinubu tún rọ àwọn Mùsùlùmí láti máa ṣe ìfẹ́ àti ìfẹ́ inú rere sí àwọn aláìní, láìka ẹ̀sìn sí, gẹ́gẹ́ bí ìfihàn ìṣọ̀kan àti ọpọ ènìyàn tí wọ́n jọ n ṣe pọ̀.
Ó tún rọ àwọn olórí ẹ̀sìn láti lo ayẹyẹ Eid-el-Fitr láti gbàdúrà fún àlàáfíà, ìdúróṣinṣin, àti àṣeyọrí tó pẹ́ títí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Temitọ́pè Òbísẹ̀san