Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari Ṣáájú Ìgbìmọ̀ Ìpolongo Ìbó Ààrẹ Tí Ẹ̀gbẹ̀ APC

0 336

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ní yóò dárí Ìpolongo ìbó Ààrẹ All Progressives Congress, APC.

Àwọn àkójọ tó jẹ́ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ irinwo le mejilelogun (422) ní Akọ̀wé Ìpolongo ìbó, Ọgbẹni James Faleke tí fí ọwọ sí.

Nínú àkójọ náà, Olùdijé Ààrẹ labẹ àsìá APC, Bola Tinubu àti Alága gbogbogbò ẹ̀gbẹ́, Sẹnatọ Abdullahi Adamu ló jẹ́ Igbákejì alága àti Olùdarí ìpolongo ìbó, nígbà tí Igbákejì olùdijé Ààrẹ, Alàgbà Kashim Shettima ní Igbákejì Alága.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Plateau ní Olùdarí Gbogbogbò tí ìpolongo náà. Alága ẹgbẹ́ APC tẹlẹ rí, Adams Oshiomhole ní Igbákejì Olùdarí Àgbà, íṣẹ́ (operations) nígbà ti Hadiza Bala Usman ní Igbákejì Olùdarí Gbogbogbò, alabojuto (Admin).

Ìwé náà tún fihàn pé gbogbo àwọn Gómìnà APC jẹ́ alàkóso ìgbìmọ̀ ìpolongo ìbó Ààrẹ ní àwọn ìpínlẹ̀ wọ́n àti ìpínlẹ̀ ti wọ́n kò bá ti ní Gómìnà ọmọ ẹgbẹ́, àwọn olùdijé Gómìnà ní àwọn alàkósó.

Akọ̀wé Ìgbìmọ̀ Ìpolongo ìbó, Ọ̀gbéní James Faleke gbà gbogbo àwọn tí wọ́n yan lamọran láti gbà ìwé yíyan wọ́n ní olù-ilé ìpolongo ìbó (Campaign Headquarters) ní Abùjá lọ́jọ́ Ajé, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣù kesan-an.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button